Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Borí Ìwà Ẹ̀tanú

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Borí Ìwà Ẹ̀tanú

Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú. (Iṣe 10:34, 35) Ó tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Iṣi 7:9) Torí náà, ìjọ Kristẹni kò fàyè gba ìwà ẹ̀tanú, a ò sì ń gbè sẹ́yìn ẹnì kankan. (Jak 2:1-4) Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe, a sì ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti yí ìwà wa pa dà sí rere. (Ais 11:6-9) Bá a ṣe ń sapá láti fa ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìwà ẹ̀tanú tu kúrò lọ́kàn wa, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ aláfarawé Ọlọ́run.Ef 5:1, 2.

WO FÍDÍÒ NÁÀ JOHNY ÀTI GIDEON: Ọ̀TÁ NI WỌ́N TẸ́LẸ̀, WỌ́N TI DI ARÁKÙNRIN BÁYÌÍ. KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ṣàǹfààní ju ìsapá àwọn èèyàn láti fòpin sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀tanú?

  • Kí ló wú ẹ lórí nípa ẹ̀gbẹ́ ará wa tó kárí ayé?

  • Báwo la ṣe ń gbé Jèhófà ga tá a bá mú kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ?