Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 11-16

Ilẹ̀ Ayé Yóò Kún fún Ìmọ̀ Jèhófà

Ilẹ̀ Ayé Yóò Kún fún Ìmọ̀ Jèhófà

Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára

  • Kò sí ìdí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti bẹ̀rù àwọn ẹranko ẹhànnà tàbí àwọn ẹhànnà èèyàn nígbà tí wọ́n ń pa dà sí ìlú wọn láti ìgbèkùn ní Bábílónì àti nígbà tí wọ́n dé ìlú wọn.Ẹsr 8:21, 22

Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe kàn wá lóde òní

  • Ìmọ̀ Jèhófà ti mu káwọn èèyàn yí ìwà wọn pa dà sí rere. Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ oníjàgídíjàgan tẹ́lẹ̀ ti wá di èèyàn jẹ́jẹ́. Ìmọ̀ Ọlọ́run ti mú ká wà nínú Párádísè tẹ̀mí tó kárí ayé

Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú

  • Ayé máa yí pa dà di Párádísè, àlááfíà á sì wà níbi gbogbo bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Kò sí ẹ̀dá kankan tó máa dẹ́rù bà wá, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko

Ìmọ̀ Ọlọ́run yí Pọ́ọ̀lù pa dà sí rere

  • Nígbà tó ṣì jẹ́ Farisí, ìwà ẹhànnà ló kún ọwọ́ rẹ̀.1Ti 1:13

  • Ìmọ̀ Ọlọ́run tó ní ló jẹ́ kó yíwà pa dà.Kol 3:8-10