December 26– January 1
AÍSÁYÀ 17-23
Orin 123 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àṣẹ Máa Ń Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹni Tó Bá Ń Ṣi Agbára Lò”: (10 min.)
Ais 22:15, 16
—Ṣẹ́bínà hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan nígbà tó wà nípò àṣẹ (ip-1 ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 16 àti 17) Ais 22:17-22
—Jèhófà fi Élíákímù rọ́pò Ṣẹ́bínà (ip-1 ojú ìwé 238 àti 239 ìpínrọ̀ 17 àti 18) Ais 22:23-25
—Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ṣẹ́bínà kọ́ wa (w07 1/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 6; ip-1 ojú ìwé 240 àti 241 ìpínrọ̀ 19 àti 20)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ais 21:1
—Àgbègbè wo ni Bíbélì pè ní “aginjù òkun,” kí sì nìdí? (w06 12/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3) Ais 23:7, 18
—Báwo ni àwọn ohun ìní tí Tírè jèrè ṣe jẹ́ “ohun mímọ́ lójú Jèhófà”? (ip-1 ojú ìwé 253 àti 254 ìpínrọ̀ 22 sí 24) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 17:
1-14
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh
—Lo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? láti fi nasẹ̀ ìwé náà. (Àkíyèsí: Ẹ má ṣe wo fídíò yìí nígbà àṣefihàn náà.) Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh
—Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà, kó o sì jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv ojú ìwé 150 àti 151 ìpínrọ̀ 10 àti 11
—Fi béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ hàn.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 44
Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?: (8 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ March 15, 2015, ojú ìwé 12 sí 16. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa ṣọ́nà, bíi ti olùṣọ́ tí wòlíì Aísáyà rí nínú ìran àtàwọn wúńdíá márùn-ún inú àkàwé Jésù.
—Ais 21:8; Mt 25:1-13. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe: (7 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù December.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 6 ìpínrọ̀ 1 sí 7, àti “APÁ 2
—Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run— À Ń Tan Ìhìn Rere Kárí Ayé” Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 141 àti Àdúrà