December 5- 11
AÍSÁYÀ 1-5
Orin 107 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Jẹ́ Kí A Gòkè Lọ sí Òkè Ńlá Jèhófà”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Aísáyà.]
Ais 2:2, 3
—“Òkè ńlá ilé Jèhófà” dúró fún ìjọsìn tòótọ́ (ip-1 ojú ìwé 38 sí 41 ìpínrọ̀ 6 sí 11 àti ojú ìwé 44 àti 45 ìpínrọ̀ 20 àti 21) Ais 2:4
—Àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà kò kọ́ṣẹ́ ogun jíjà mọ́ (ip-1 ojú ìwé 46 àti 47 ìpínrọ̀ 24 àti 25)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ais 1:8, 9
—Ọ̀nà wo la ó gbà fi ọmọbìnrin Síónì “sílẹ̀ bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà”? (w06 12/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5) Ais 1:18
—Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa”? (w06 12/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1; it-2-E ojú ìwé 761 ìpínrọ̀ 3) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 5:1-13
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú láti kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (7 min.) Ẹ tún lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 34 ìpínrọ̀ 1)
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I
—Máa Lo Ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ Láti Dénú Ọkàn Àwọn Èèyàn”: (8 min.) Ìjíròrò. Gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní iṣẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣù yìí níyànjú pé kí wọ́n fi ìmọ̀ràn tó wà lójú ìwé 261 àti 262 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́runsílò. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 5 ìpínrọ̀ 1 sí 9
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 154 àti Àdúrà
Ìránnilétí: Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.