Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I— Máa Lo Ìwé “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run” Láti Dénú Ọkàn Àwọn Èèyàn

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I— Máa Lo Ìwé “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run” Láti Dénú Ọkàn Àwọn Èèyàn

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìlànà Jèhófà kí wọ́n sì máa fi wọ́n sílò, kí wọ́n báa lè ṣe ìjọsìn tí Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà. (Ais 2:3, 4) Ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run,” tó jẹ́ ìwé kejì tá a máa ń fi kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lẹ́kọ̀ọ́ máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fí àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò. (Heb 5:14) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti dénú ọkàn wọn nígbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n báa lè rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn.Ro 6:17.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Múra sílẹ̀ dáadáa, kó o sì ronú nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ nílò. Béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ èrò rẹ̀ àti bí ohun tẹ́ ẹ kọ́ ṣe rí lára rẹ̀.Owe 20:5; be ojú ìwé 259

  • Lo àwọn àpótí tó wà nínú ìwé náà kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lè mọ pé ó ṣe pàtàkì láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì

  • Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ọ̀ràn tó dá lórí ẹ̀rí ọkàn, àmọ́ má ṣe pinnu fún un.Ga 6:5

  • Lo ọgbọ́n kó o lè mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ nílò ìrànlọ́wọ́ kó lè máa fi ìlànà Bíbélì pàtó kan sílò. Kó o sì fún un ní ìṣírí kó lè ṣe àtúnṣe nítorí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà.Owe 27:11; Jo 14:31