‘Ẹ Jẹ́ Kí A Gòkè Lọ sí Òkè Ńlá Jèhófà’
“Apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” |
Àkókò tí à ń gbé yìí |
“Òkè ńlá ilé Jèhófà” |
Ìjọsìn mímọ́ tó jẹ́ ti Jèhófà |
“Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀” |
Àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ máa ń pàdé pọ̀ ní ìṣọ̀kan |
“Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà” |
Àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ máa ń pe àwọn míì láti dara pọ̀ mọ́ wọn |
“Òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ” |
• Jèhófà máa ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà àti láti ràn wá lọ́wọ́, ká lè máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ |
“Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́” |
Aísáyà ṣàpèjúwe bá a ṣe máa yí àwọn ohun ìjà ogun pa dà sí ohun èlò téèyàn lè fi ṣiṣẹ́ oko, tó fi hàn pé àlááfíà láwọn èèyàn Jèhófà á máa wá. Kí làwọn ohun èlò yìí nígbà ayé Aísáyà? |
‘Wọn yóò fi idà rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀’ |
1 Abẹ ohun ìtúlẹ̀ ni ohun èlò kan tí wọ́n fi máa ń wú ilẹ̀. Irin ni wọ́n fi máa ń ṣe àwọn kan. |
‘Wọn yóò fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn’ |
2 Irin ni wọ́n fi ń ṣe ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn, ó máa ń rí kọrọdọ, ó sì mú. Ó máa ń ní ibi téèyàn ti lè dì í mú. Ohun èlò yìí wúlò gan-an fún rírẹ́ ọwọ́ àjàrà. |