Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​​—Ran Àwọn Tó Ní “Ìtẹ̀sí-Ọkàn Títọ́” Lọ́wọ́ Láti Di Ọmọlẹ́yìn

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​​—Ran Àwọn Tó Ní “Ìtẹ̀sí-Ọkàn Títọ́” Lọ́wọ́ Láti Di Ọmọlẹ́yìn

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Jèhófà máa ń mú kí irúgbìn òtítọ́ hù lọ́kàn àwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Iṣe 13:48; 1Kọ 3:7) Tá a bá ń fi gbogbo okun wa wá àwọn tó máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, ṣe là ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́. (1Kọ 9:26) Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì kí àwọn tó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. (1Pe 3:21) Tá a bá fẹ́ kí wọ́n di ọmọlẹ́yìn, a gbọ́dọ̀ máa kọ́ wọn kí wọ́n bàa lè ṣe àwọn àyípadà tó yẹ ní ìgbésí ayé wọn, kí àwọn náà máa wàásù, kí wọ́n máa kọ́ni, kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.​—Mt 28:19, 20.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Máa rán àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì létí pé, ìdí tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ ni pé, kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀.​—Jo 17:3

  • Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro, irú bí àwọn àṣàkaṣà tí Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́

  • Kí wọ́n tó ṣe ìrìbọmi, fún wọn níṣìírí, lẹ́yìn ìrìbọmi, tún fún wọn níṣìírí.​—Iṣe 14:22

WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí làwọn ìdí tẹ́nì kan fi lè máa bẹ̀rù láti ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?

  • Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?

  • Kí ni Aísáyà 41:10 kọ́ wa nípa Jèhófà?

  • Lóòótọ́ a kì í ṣe ẹni pípé, àmọ́ ànímọ́ wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti sin Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà?

Báwo la ṣe lè bá Jèhófà ṣiṣẹ́ pọ̀ tá a bá ń wá àwọn tó máa di ọmọlẹ́yìn?