December 17-23
ÌṢE 15-16
Orin 96 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Wọ́n Fìmọ̀ Ṣọ̀kan Láti Ṣe Ìpinnu Tó Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”: (10 min.)
Iṣe 15:1, 2—Ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ fẹ́ fa ìyapa láàárín ìjọ Kristẹni tuntun (bt 102-103 ¶8)
Iṣe 15:13-20—Orí Ìwé Mímọ́ ni ìgbìmọ̀ olùdarí gbé ìpinnu wọn kà (w12 1/15 5 ¶6-7)
Iṣe 15:28, 29; 16:4, 5—Ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe ìpinnu tó fún ìjọ lókun (bt 123 ¶18)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Iṣe 16:6-9—Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí nípa bá a ṣe lè mú kí iṣẹ́ ìsìn wa gbòòrò sí i? (w12 1/15 10 ¶8)
Iṣe 16:37—Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù tó ní láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i? (“a jẹ́ ará Róòmù” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 16:37, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Iṣe 16:25-40
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Sọ̀rọ̀ nípa fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó).
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Fi Orin Yin Jèhófà”: (15 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà Àwọn Ọmọdé Ń Fi Orin Yin Jèhófà. Láti parí apá yìí, sọ pé kí gbogbo àwọn ará dìde dúró kẹ́ ẹ sì jọ kọrin pẹ̀lú fídíò Orin 084 Wá Wọn Lọ.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 17 ìpínrọ̀ 11-22
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 102 àti Àdúrà