Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Orin Yin Jèhófà

Fi Orin Yin Jèhófà

Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi orin yin Jèhófà nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n. (Iṣe 16:25) Ó dájú pé orin tí wọ́n ń kọ yẹn fún wọn lókun láti fara da ipò tí wọ́n wà. Àwa náà ńkọ́ lónìí? Tá a bá wà nínú ìṣòro, àwọn orin tá à ń lò ní ìpàdé àti àwọn orin tí wọ́n fẹnu kọ máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Àmọ́ ju gbogbo ìyẹn lọ, àwọn orin yẹn tún máa ń fìyìn fún Jèhófà. (Sm 28:7) Ó ti pẹ́ tí ètò Ọlọ́run ti máa ń rọ̀ wá pé ká gbìyànjú láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sórí. Ṣé o ti ṣe bẹ́ẹ̀? A lè fi àwọn orin yẹn dánra wò ká sì kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn nígbà ìjọsìn ìdílé.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN ỌMỌDÉ Ń FI ORIN YIN JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Tá a bá ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run, àǹfààní wo ló máa ṣe fún wa?

  • Báwo làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń gbohùn sílẹ̀ ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún àwọn tó fẹ́ wá kọrin?

  • Báwo làwọn ọmọdé àti ìdílé wọn ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún orin tí wọ́n fẹ́ lọ kọ?

  • Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wo lo fẹ́ràn jù, kí sì nìdí?