Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọ kan ń tẹ́tí sí ìpinnu tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 15-16

Wọ́n Fìmọ̀ Ṣọ̀kan Láti Ṣe Ìpinnu Tó Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Wọ́n Fìmọ̀ Ṣọ̀kan Láti Ṣe Ìpinnu Tó Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí wọ́n ṣe yanjú ìṣòro náà?

15:1, 2—Jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti onísùúrù. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò fi ọgbọ́n ara wọn yanjú ọ̀rọ̀ náà, ṣe ni wọ́n béèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ ètò Ọlọ́run.

15:28, 29—Fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Ó dá ìjọ lójú pé Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti Jésù láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.

16:4, 5—Jẹ́ onígbọràn. Àwọn ìjọ ń pọ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ìgbìmọ̀ olùdarí ń fún wọn.