December 16-22
ÌFIHÀN 13-16
Orin 55 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Má Ṣe Bẹ̀rù Àwọn Ẹranko Abàmì Náà”: (10 min.)
Ifi 13:1, 2—Dírágónì náà fún ẹranko olórí méje àti oníwo mẹ́wàá náà ní ọlá àṣẹ (w12 6/15 8 ¶6)
Ifi 13:11, 15—Ẹranko oníwo méjì náà mí èémí ìyè sínú ère ẹranko àkọ́kọ́ (re 193 ¶26; 194-195 ¶30-31)
Ifi 13:16, 17—Má ṣe gba àmì ẹranko náà (w09 2/15 4 ¶2)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ifi 16:13, 14—Kí ló máa mú káwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé kóra jọ fún “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè”? (w09 2/15 4 ¶5)
Ifi 16:21—Kí làwa èèyàn Jèhófà á máa kéde tó bá kù díẹ̀ kí ayé Sátánì pa run? (w15 7/15 16 ¶9)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ifi 16:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà, ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 11)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Má Ṣe Dá Sọ́rọ̀ Ogun àti Òṣèlú: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Má Ṣe Dá Sọ́rọ̀ Ogun àti Òṣèlú Nínú Èrò àti Ìṣe Rẹ. Lẹ́yìn náà béèrè pé, kí la lè ṣe tá ò fi ní dá sọ́rọ̀ òṣèlú tàbí àwọn rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ? Ẹ tún wo fídíò Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Tó O Bá Wà Níbi Tí Wọ́n Ti Ń Kí Àsíá. Lẹ́yìn náà, béèrè pé, báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ fáwọn ipò tó lè fẹ́ mú ká lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 13 ¶17-19
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 131 àti Àdúrà