December 23-29
ÌFIHÀN 17-19
Orin 149 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ogun Tó Máa Fòpin sí Gbogbo Ogun”: (10 min.)
Ifi 19:11, 14-16—Jésù Kristi máa pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run (w08 4/1 8 ¶3-4; it-1 1146 ¶1)
Ifi 19:19, 20—Ẹranko náà àti wòlíì èké náà máa pa run (re 285 ¶24)
Ifi 19:21—Gbogbo èèyàn tó bá ń ta ko Jèhófà Ọba Aláṣẹ máa pa run (re 286 ¶25)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ifi 17:8—Ṣàlàyé bí “ẹranko náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí kò sí, síbẹ̀ tó tún máa wà.” (re 247-248 ¶5-6)
Ifi 17:16, 17—Báwo la ṣe mọ̀ pé òjijì ni ẹ̀sìn èké máa pa run, tí kì í ṣe pé á máa pòórá díẹ̀díẹ̀? (w12 6/15 18 ¶17)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ifi 17:1-11 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 8)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) jl ẹ̀kọ́ 8 (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò orin Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Àwọn ipò wo nígbèésí ayé wa ló ti lè gba pé ká lo ìgboyà? Ìtàn Bíbélì wo ló máa ń fún ẹ nígboyà? Àwọn wo ló wà lẹ́yìn wa? Ní ìparí apá yìí, ní káwọn ará dìde dúró, kẹ́ ẹ sì jọ kọ orin náà “Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà” (èyí tó lọ́rọ̀ orin).
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 14 ¶1-7
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 136 àti Àdúrà