Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 17-19

Ogun Tó Máa Fòpin sí Gbogbo Ogun

Ogun Tó Máa Fòpin sí Gbogbo Ogun

19:11, 14-16, 19-21

Kí nìdí tí Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà” fi yan Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” láti ja ogun kan?​2Kọ 13:11; Ais 9:6.

  • Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ òdodo, wọ́n sì kórìíra ìwà burúkú

  • Ó dìgbà táwọn èèyàn burúkú ò bá sí mọ́ ká tó lè gbádùn àlàáfíà tòótọ́, kí ìdájọ́ òdodo sì gbilẹ̀

  • Aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa, tó funfun, tó sì mọ́ tónítóní táwọn ọmọ ogun ọ̀run wọ̀ fi hàn pé wọ́n ń “fi òdodo jagun lọ.”

Kí ló yẹ ká ṣe ká lè la ogun pàtàkì yìí já?​—Sef 2:3