December 14-20
LÉFÍTÍKÙ 12-13
Orin 140 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Òfin Nípa Àrùn Ẹ̀tẹ̀”: (10 min.)
Le 13:4, 5—Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn èèyàn tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ́tọ̀ (wp18.1 7)
Le 13:45, 46—Ẹni tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn kó má bàa kó o ràn wọ́n (wp16.4 9 ¶1)
Le 13:52, 57—Wọ́n gbọ́dọ̀ sun ohunkóhun tí àrùn náà bá wà lára ẹ̀ (it-2 238 ¶3)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Le 13:9-28 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Ìjíròrò. E wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè pé: Báwo ni Tóyìn ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó yẹ? Báwo ló ṣe jẹ́ kí onílé lóye ẹsẹ Bíbélì tó kà?
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 19)
Ìpadàbẹ̀wò: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀kọ́ 11. (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (15 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) rr orí 2 ¶1-9 àti fídíò ohun tó wà ní orí 2
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 28 àti Àdúrà