A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ju Ìdílé Wa Lọ
Tí wọ́n bá yọ èèyàn wa kan lẹ́gbẹ́, ó lè nira fún wa láti pinnu ẹni tó yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí. Ìtọ́ni tí Jèhófà fún Áárónì jẹ́ ká rí i pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún mọ̀lẹ́bí wa tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára ju ìfẹ́ tá a ní fún mọ̀lẹ́bí wa tó jẹ́ aláìṣòótọ́.
Àwọn ìbùkún wo la máa rí tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jèhófà fún wa nípa bó sẹ yẹ ká máa ṣe sáwọn tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́?—1Kọ 5:11; 2Jo 10, 11