Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

February 15 sí 21

NEHEMÁYÀ 9-11

February 15 sí 21
  • Orin 84 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé” tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ṣe àṣefihàn kan. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.

  • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé” tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (bh ojú ìwé32 sí 33 ìpínrọ̀ 13 àti 14)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 19

  • Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ”: (15 min.) Ìjíròrò. Kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò yìí. Lẹ́yìn náà, jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí. Ní ṣókí, fi ọ̀rọ̀ wá akéde kan lẹ́nu wò. Ó lè jẹ́ ẹni tó ti ṣègbéyàwó tàbí ẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó. Akéde náà ti lo àǹfààní ọ̀pọ̀ ọdún tó fi wà láì lọ́kọ tàbí láì láya láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1Kọ 7:35) Àwọn ìbùkún wo ló ti rí gbà?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 13 (30 min.)

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 76 àti Àdúrà