February 29 sí March 6
Ẹ́SÍTÉRÌ 1-5
Orin 86 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ́sítérì Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítérì.]
Es 3:5-9
—Hámánì fẹ́ pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run (ia ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 18 àti 19) Es 4:11–5:2
—Ìgbàgbọ́ tí Ẹ́sítérì ní borí ìbẹ̀rù ikú (ia ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 2; ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 24 sí 26)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Es 2:15
—Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn? (w06 3/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7) Es 3:2-4
—Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (ia ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 18) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Ẹst 1:1-15 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọ ẹnì kan. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Ẹ jọ jíròrò ojú ìwé 2 àti 3. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi ojú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹni tó gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run nígbà àkọ́kọ́. (km 7/12 ojú ìwé 2 sí 3 ìpínrọ̀ 4)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 71
Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ: (10 min.)
Báwo Lo Ṣe Ń Jàǹfààní Nínú Ọ̀nà Tuntun Tá A Gbà Ń Ṣèpàdé àti Ìwé Ìpàdé?: (5 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nínú ìpàdé tuntun yìí. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n lè máa jàǹfààní gan-an nínú rẹ̀.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 10 ìpínrọ̀ 1 sí 11 àti àpótí tó wà lójú ìwé 86 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 149 àti Àdúrà