Arábìnrin kan ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ní kíláàsì

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI February 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! lọni àti láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ẹlẹ́dàá. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Máa Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣègbọ́ràn Sí I

Jèhófà Ọlọ́run fi ọ̀nà tí a ó máa rìn hàn wá, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kristi Jìyà fún Wa

Ikú Jésù fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì pa pé àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò lè jẹ́ adúróṣinṣin sí i.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Nínú Ẹlẹ́dàá

Kí làwọn ọmọ rẹ gbà gbọ́ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Pòkìkí Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà Níhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà”

Ṣé ọdún orí kalẹ́ńdà ni ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà? Báwo ni àkókò náà ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa

Kì í ṣe owó kékeré là ń ná láti ṣe àwọn ìtẹ̀jáde wa ká sì kó wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ jákèjádò ayé. Torí náà, lo ìfòyemọ̀ tó o bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé wa.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun Máa Mú Ká Láyọ̀ Tó Kọ Yọyọ

Kí ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” túmọ̀ sí fún wa lónìí?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kí Ìrètí Tó O Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀

Ńṣe ni ìrètí dà bí ìdákọ̀ró. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ìlérí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa jẹ́ ká láyọ̀, a ó sì jẹ́ olóòótọ́ láìka àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì líle sí.