MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Nínú Ẹlẹ́dàá
Ìṣẹ̀dá ń polongo ògo Jèhófà. (Sm 19:1-4; 139:14) Àmọ́, àwọn ẹ̀kọ́ tí kò fi ògo fún Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá ni ayé Èṣù yìí ń gbé lárugẹ. (Ro 1:18-25) Kí lo lè ṣe tírú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kò fi ní gbilẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ rẹ, kó sì sọ ìrònú wọn dìdàkudà? Láti kékeré ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ràn wọ́n lọ́wọ́, kó lè dá wọn lójú pé Jèhófà wà àti pé ó kà wọ́n sí pàtàkì. (2Kọ 10:4, 5; Ef 6:16) Fọgbọ́n wádìí àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn níléwèé, kó o sì lo onírúurú ohun èlò ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti dénú ọkàn wọn.
JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ
Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ nípa Ọlọ́run?
Kí ni wọ́n ń kọ́ yín níléwèé?
Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà wà?
Báwo lo ṣe lè fèròwérò pẹ̀lú ẹnì kan kó lè gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo?