Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 58-62

“Pòkìkí Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà Níhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà”

“Pòkìkí Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà Níhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà”

“Ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà” kì í ṣe ọdún orí kàlẹ́ńdà

61:1, 2

  • Ó jẹ́ àkókò kan tí Jèhófà fún àwọn ọlọ́kàn tútù láǹfààní láti gbọ́ ìkéde òmìnira, kí wọ́n sì ṣe ìpinnu

  • Ní ọ̀rúndún kìíní, ọdún ìtẹ́wọ́gbà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ó sì parí ní “ọjọ́ ẹ̀san” Jèhófà, ìyẹn lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run

  • Ní àkókò wa, ọdún ìtẹ́wọ́gbà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́run ní ọdún 1914, ó sì máa parí nígbà ìpọ́njú ńlá

Jèhófà ń fi “igi ńlá òdodo” bù kún àwọn èèyàn rẹ̀

61:3, 4

  • Àwọn igi tó ga jù láyé sábà máa ń dàgbà pa pọ̀, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́

  • Àwọn ìtàkùn wọn máa ń so kọ́ra, èyí sì máa ń mú kí wọ́n lè fìdí múlẹ̀ dáadáa débi tí ìjì ò fi ní lè fà wọ́n tu

  • Àwọn igi ńlá máa ń ṣíji bo àwọn igi kéékèèké tó wà lábẹ́ wọn, àwọn ewé tó sì ń jábọ́ lórí rẹ̀ máa ń mú kí ilẹ̀ lọ́ràá

“Igi ńlá òdodo” náà, ìyẹn àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ń ṣètìlẹ́yìn fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni kárí ayé, wọ́n sì ń dáàbò bò wọ́n