ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI February 2018
Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
Ìjíròrò tó dá lórí ìbéèrè náà: Ṣé Bíbélì ṣì wúlò lóde òní? Ṣé Bíbélì àti sáyẹ́ǹsì bára mu? Ǹjẹ́ àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì ṣì wúlò?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Àkàwé Àlìkámà àti Èpò
Àlàyé wo ni Jésù ń ṣe nínú àkàwé rẹ̀? Tani afúnrúgbìn, ọ̀tá, àtàwọn olùkórè?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àǹfààní Tá A Lè Rí Nínú Ìtumọ̀ Àwọn Àpèjúwe Ìjọba Ọlọ́run
Jésù lo àwọn àpèjúwe tó rọrùn láti kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ẹ̀kọ́ tẹ̀mí tó jinlẹ̀. Kí la tún rí kọ́ nínú Mátíù orí 13?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì ni wọ́n ní. Kí ló ṣẹlẹ̀, kí ló sì túmọ̀ sí fún wa?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ pàtàkì náà: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” Ǹjẹ́ ìgbà kan wà tí kò ṣe pàtàkì mọ́ pé ká máa bọlá fún àwọn òbí wa?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Èrò Ta Ni Ò Ń Rò?
Tá a bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? Jésù jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta tó máa jẹ́ ká yẹra fún èrò tí kò tọ́.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
Jésù lo oríṣiríṣi ìbéèrè tó gbéṣẹ́ kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Báwo la ṣe lè máa kọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bíi ti Jésù?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Yẹra Pátápátá fún Ohun Tó Lè Mú Ìwọ Àtàwọn Mí ì Kọsẹ̀
Jésù lo àpèjúwe láti kọ́ni nípa bó ṣe léwu tó láti kọsẹ̀ tàbí láti mú kí ẹlòmí ì kọsẹ̀. Àwọn nǹkan wo lò ń fi ayé rẹ ṣe tó lè di ohun ìkọ̀sẹ̀?