Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

February 12-​18

MÁTÍÙ 14-15

February 12-​18
  • Orin 93 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn”: (10 min.)

    • Mt 14:​16, 17​—Ohun tó wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò ju búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì (w13 7/15 15 ¶2)

    • Mt 14:​18, 19​—Jésù tipasẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn (w13 7/15 15 ¶3)

    • Mt 14:​20, 21​—Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló jàǹfààní nínú iṣẹ́ ìyanu Jésù (“àtàwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 14:21, nwtsty; w13 7/15 15 ¶1)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Mt 15:​7-9​—Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún àgàbàgebè? (“alágàbàgebè” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 15:7, nwtsty)

    • Mt 15:26​—Kí ló ṣeé ṣe kí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ajá kéékèèké”? (“àwọn ọmọdé . . . àwọn ajá kéékèèké” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 15:26, nwtsty )

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 15:​1-20

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.

  • Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́ ​—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

  • Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w15 9/15 16-17 ¶14-17​—Àkòrí: Máa Wo Jésù Kó O sì Fún Ìgbàgbọ́ Rẹ Lókun.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 135

  • Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà ​—Bó O Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́: (7 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé tó o ti yàn wá sórí pèpéle, kí o sì bi wọ́n ní àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi yẹ kó o yan àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Kí lo lè kọ́ lára wọn?

  • Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo eré ojú pátákó náà Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Sọ Tinú Mi Fáwọn Òbí Mi?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 4 ¶1-11

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 148 àti Àdúrà