Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”

“Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ”

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ pàtàkì náà: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹk 20:12; Mt 15:⁠4) Jésù lẹ́nu ọ̀rọ̀ torí pé ó ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ̀ nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. (Lk 2:51) Nígbà tó sì dàgbà, ó ṣètò pé kí ẹnì kan máa tọ́jú ìyá rẹ̀ tí òun bá kú. ​—⁠Joh 19:​26, 27.

Bákan náà, lóde òní, tí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni bá ń gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu tí wọ́n sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn ń bọlá fún wọn. Àṣẹ yìí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Kódà, bí àwọn òbí wa bá tiẹ̀ ti darúgbó pàápàá, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti bọlá fún wọn ká sì máa jàǹfààní látinú ọgbọ́n wọn. (Owe 23:22) Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà bọlá fún àwọn òbí wa ni pé ká máa bójú tó ìmọ̀lára wọn àti ìnáwó wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. (1Ti 5:⁠8) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí a ti dàgbà, tá a bá ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn òbí wa, ńṣe là ń fi hàn pé a bọlá fún wọn.

WO ERÉ OJÚ PÁTÁKÓ NÁÀ BÁWO NI MO ṢE LÈ MÁA SỌ TINÚ MI FÁWỌN ÒBÍ MI? LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló lè mú kó ṣòro fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀?

  • Báwo lo ṣe lè bọlá fún àwọn òbí rẹ tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀?

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa sapá láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀? (Owe 15:⁠22)

    Tó o bá ń bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀, èyí lè mú kó o túbọ̀ ṣe àṣeyọrí ní ìgbésí ayé rẹ