Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 16-17

Èrò Ta Ni Ò Ń Rò?

Èrò Ta Ni Ò Ń Rò?

16:21-23

  • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa ló wà lọ́kàn Pétérù, Jésù tètè tún èrò òdí tí Pétérù ní ṣe

  • Jésù mọ̀ pé àkókò yẹn kọ́ ló yẹ kí òun “ṣàánú” ara òun. Ohun tí Sátánì fẹ́ gan-an ni pé kí Jésù dẹwọ́ ní àkókò pàtàkì yẹn

16:24

Jésù jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn túmọ̀ sí?

  • Sẹ́ ara rẹ

  • Gbé òpó igi oró rẹ

  • Máa tọ Kristi lẹ́yìn