Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 18-19

Yẹra Pátápátá fún Ohun Tó Lè Mú Ìwọ Àtàwọn Mí ì Kọsẹ̀

Yẹra Pátápátá fún Ohun Tó Lè Mú Ìwọ Àtàwọn Mí ì Kọsẹ̀

Jésù lo àpèjúwe láti kọ́ni nípa bó ṣe léwu tó láti kọsẹ̀ tàbí láti mú kí ẹlòmíì kọsẹ̀.

18:6, 7

  • “Ohun ìkọ̀sẹ̀” túmọ̀ sí ìwà kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó mú kí ẹnì kan ṣe ohun tí kò tọ́, kó kọsẹ̀, kó hùwàkiwà tàbí kó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀

  • Ó sàn fún ẹnì kan pé kí á so ọlọ ńlá kọ́ ọrùn rẹ̀ kí ó sì bẹ́ sínú òkun ju pé kí ó mú ẹlòmíì kọsẹ̀

Ọlọ ńlá

18:8, 9

  • Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n mú ohunkóhun tó lè mú wọn kọsẹ̀ kúrò, kódà kó jẹ́ ohun tó ṣeyebíye bí ojú tàbí apá wọn

  • Ó sàn ká pàdánù ohun tó ṣeyebíye bẹ́ẹ̀ ká lè wọ inú Ìjọba Ọlọ́run ju pé kí wọ́n mú wa kọsẹ̀ ká wá lọ parí ayé wa sínú Gẹ̀hẹ́nà, tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé

Àwọn nǹkan wo ni mò ń fi ayé mi ṣe tó lè di ohun ìkọ̀sẹ̀, báwo ni mo ṣe lè yẹra pátápátá fún ohun tó lè mú èmi tàbí àwọn míì kọsẹ̀?