Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 4-6

“Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Tirẹ̀ fún Wa”

“Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Tirẹ̀ fún Wa”

5:8, 18, 21

Ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà fún wa ló máa jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ di mímọ́, ó tún máa fi hàn pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àti ọ̀run àti pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dáa jù lọ. Ìràpadà ló tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, òun náà ló máa jẹ́ kí àwọn tó bá tẹ́tí sí Ọlọ́run wà láàyè títí láé.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn ìràpadà yìí?

  • Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà àti pé ti Jèhófà la fẹ́ ṣe

  • Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run fi hàn pé irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí gbogbo èèyàn ni àwa náà ń fara wé.​—Mt 22:39; Jo 3:16

Àwọn ọ̀nà míì wo ni mo lè gbà fi hàn pé mo mọrírì ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà fún wa?