Àpèjúwe Igi Ólífì
Kí ni apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lára igi náà dúró fún?
-
Igi náà: dúró fún bí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣe ní ìmúṣẹ
-
Ìtì igi náà: dúró fún Jésù tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ Ábúráhámù
-
Àwọn ẹ̀ka: dúró fún apá kejì lára irú ọmọ Ábúráhámù
-
Àwọn ẹ̀ka tá a ṣẹ́ kúrò: dúró fún àwọn Júù nípa tara tí wọ́n kọ Jésù sílẹ̀
-
Àwọn ẹ̀ka tá a lọ́ mọ́ ọn: dúró fún àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn lára àwọn orílẹ̀-èdè
Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, irú ọmọ Ábúráhámù, ìyẹn Jésù àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa mú ìbùkún wá fún “àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè.”—Ro 11:12; Jẹ 22:18
Kí ni mo kọ́ lára Jèhófà nínú ọ̀nà tó gbà mú ìlérí tó ṣe nípa irú ọmọ Ábúráhámù ṣẹ?