Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Fòpin Sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Kò Méso Jáde

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Fòpin Sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Kò Méso Jáde

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Káwọn èèyàn tó lè rí ìgbàlà, wọ́n gbọ́dọ̀ ké pe orúkọ Jèhófà. (Ro 10:13, 14) Síbẹ̀ kì í ṣe gbogbo ẹni tó bá gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ṣe tán láti máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò. Ká má bàa fi àkókò wa ṣòfò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn tó ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà kí wọ́n lè múnú Jèhófà dùn ló yẹ ká ràn lọ́wọ́. Tí ẹnì kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, á dáa ká darí àfíyèsí wa sórí àwọn tí Jèhófà ń fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jo 6:44) Àmọ́ o, tó bá dọjọ́ iwájú, tẹ́ni náà bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó fi hàn pé òun “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun,” inú wa máa dùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pa dà.​—Iṣe 13:48.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Gbóríyìn fún ẹni náà bó ṣe ń gbìyànjú láti ní ìmọ̀ pípéye.​—1Ti 2:4

  • Tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kó máa fi ohun tó ń kọ́ sílò.​—Lk 6:46-49

  • Jíròrò àkàwé Jésù nípa afúnrúgbìn pẹ̀lú rẹ̀, kó o sì béèrè ohun tó ṣeé ṣe kó máa dí i lọ́wọ́ láti fi ohun tó ń kọ́ sílò.​—Mt 13:18-23

  • Fọgbọ́n ṣàlàyé ìdí tó o fi fẹ́ dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró

  • Jẹ́ kó mọ̀ pé wàá máa pè é lóòrèkóòrè láti máa fún un ní ìṣírí àti pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tó ń kọ́ sílò, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa dà

WO FÍDÍÒ NÁÀ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí lo rí nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yẹn tó fi hàn pé ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ò fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?

  • Báwo ni akéde yẹn ṣe jẹ́ kí ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ó ní láti ṣàtúnṣe?

  • Báwo ni akéde yẹn ṣe jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ mọ̀ pé tó bá ṣe ohun tó yẹ, òun ṣe tán láti máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó?