MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Máa Ń Rí Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Tí A Kò Lè Rí?
Tó o bá wo àwọn òdòdó tó rẹwà, ìràwọ̀ ojú ọ̀run tàbí àrágbáyamúyamù omi tó ń tú yaa látinú àpáta, ṣé o máa ń rí i pé iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá ni wọ́n? Àwọn ìṣẹ̀dá tó yí wa ká jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ Jèhófà lọ́nà tó ṣe kedere. (Ro 1:20) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tá à ń rí, a máa rí i pé alágbára ni Ọlọ́run, ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó gbọ́n, onídàájọ́ òdodo ni, ọ̀làwọ́ sì ni.—Sm 104:24.
Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà wo lo máa ń rí lójoojúmọ́? Kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tó ti lajú gan-an lò ń gbé, o ṣì máa rí àwọn ẹyẹ àtàwọn igi lóríṣiríṣi. Tá a bá ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, àníyàn wa máa dín kù, àwọn ìṣòro wa ò ní gbà wá lọ́kàn jù, a sì máa túbọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé. (Mt 6:25-32) Tó o bá ní àwọn ọmọ, ràn wọ́n lọ́wọ́ kí àwọn náà lè máa rí àwọn ànímọ́ Jèhófà tí kò láfiwé. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọyì àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá náà, làá máa túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa.—Sm 8:3, 4.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN ÌṢẸ̀DÁ ỌLỌ́RUN Ń FI ÒGO RẸ̀ HÀN—ÌMỌ́LẸ̀ ÀTI ÀWỌ̀, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ló máa ń jẹ́ ká rí oríṣiríṣi àwọ̀?
-
Kí nìdí tí àwọn àwọ̀ kan ṣe máa ń yí pa dà tá a bá wò ó láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
-
Kí nìdí tá a fi máa ń rí oríṣiríṣi àwọ̀ lójú ọ̀run?
-
Àwọn àwọ̀ tó o fẹ́ràn wo lo ti rí lára àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tó wà nítòsí ilé rẹ?
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wáyè wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá?