Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí máa dùn-ún gbé tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí?
Ka Bíbélì: Heb 13:18
Fi ìwé lọni: Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Torí náà, ó yẹ ká máa ṣòótọ́ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́.
ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)
Béèrè ìbéèrè: Kí lèrò rẹ nípa ìbéèrè yìí? [Ka ìbéèrè àkọ́kọ́.] Àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹni tó bá ti kú á lọ máa gbé ní ibòmíì, àwọn kan sì gbà pé ìkú ni òpin ohun gbogbo. Kí ni ìwọ gbà gbọ́?
Ka Bíbélì: Onw 9:5
Fi ìwé lọni: Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. Màá fẹ́ kó o kà á. A máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tí mo bá pa dà wá.
ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!
Fi ìwé lọni: Mo fẹ́ fi bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ hàn ọ́. Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ ibi tí wàá ti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì nínú Bíbélì rẹ.
Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o ti ka Bíbélì rí? Jẹ́ kí n fi bí àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé yìí ṣe rọrùn tó hàn ọ́. [Bá a jíròrò ìbéèrè 1 nínú ẹ̀kọ́ 2.]
Ka Bíbélì: Iṣi 4:11
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.