January 18 SÍ 24
Ẹ́SÍRÀ 1-5
Orin 85 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ”: (10 min.) [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sírà.]
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ẹsr 1:
3-6 —Ǹjẹ́ a lè sọ pé àìní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni kò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn? (w06 1/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 5; ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1) Ẹsr 4:
1-3 —Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pa dà dé láti ìgbèkùn fi kọ̀ láti gba àbá tí àwọn kan dá fún wọn? (w06 1/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 3) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Ẹsr 3:10–4:7 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (bh ojú ìwé 20 àti 21 ìpínrọ̀ 6 sí 8)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 40
“Gbogbo Nǹkan Mìíràn Wọ̀nyí Ni A Ó sì Fi Kún Un fún Yín”: (5 min.) Àsọyé tó dá lórí Mátíù 6:33 àti Lúùkù 12:
22-24. Ní kí àwọn ará sọ ìrírí tí wọ́n ní nípa bí Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tó pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara torí pé wọ́n fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn. Ǹjẹ́
—“Bẹ́ẹ̀ Ni” Rẹ Kì Í Di “Bẹ́ẹ̀ Kọ́”?: (10 min.) Ìjíròrò. (w14 3/15 ojú ìwé 30 sí 32) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 7 ìpínrọ̀ 1 sí 14 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 41 àti Àdúrà