Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
Jèhófà ṣèlérí pé òun á mú kí àwọn èèyàn òun pa dà máa jọ́sìn òun nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pa dà dé láti ìgbèkùn Bábílónì ní. Bí àpẹẹrẹ, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe dúró. Torí náà ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé àwọn ò ní lè parí iṣẹ́ náà.
-
nǹkan bí 537 Ṣ.S.K.
Kírúsì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ tún tẹ́ńpìlì kọ́
-
Oṣù keje
Wọ́n mọ pẹpẹ; wọ́n rú ẹbọ
-
536 Ṣ.S.K.
Wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀
-
522 Ṣ.S.K.
Atasásítà Ọba dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró
-
520 Ṣ.S.K.
Sekaráyà àti Hágáì gba àwọn èèyàn náà níyànjú láti pa dà sí ẹnu iṣẹ́ ìkọ́lé náà
-
515 Ṣ.S.K.
Wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì