January 25 sí 31
Ẹ́SÍRÀ 6-10
Orin 10 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́”: (10 min.)
Ẹsr 7:10
—Ẹ́sírà múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ Ẹsr 7:
12-28 —Ẹ́sírà ṣètò láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù Ẹsr 8:
21-23 —Ẹ́sírà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ẹsr 9:
1, 2 —Báwo ni ọ̀rọ̀ fífẹ́ lára “àwọn èèyàn ilẹ̀ náà” ṣe burú tó? (w06 1/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1) Ẹsr 10:3
—Kí nìdí tí wọ́n fi lé àwọn aya àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ tọmọtọmọ? (w06 1/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 2) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Ẹsr 7:
18-28 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọ ẹnì kan, ẹ jọ jíròrò ẹ̀kọ́ 8, ìbéèrè 1, ìpínrọ̀ 1. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó gba ìwé Ìròyìn Ayọ̀. Ẹ jọ jíròrò ẹ̀kọ́ 8, ìbéèrè 1, ìpínrọ̀ 2. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, fi ẹ̀kọ́ 8, ìbéèrè 2 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ ṣe é.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I
—Sọ Ohun Tó O Máa Bá Onílé Jíròrò Nígbà Tó O Bá Pa Dà Wá”: (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Sunwọ̀n Sí I Ti January táá jẹ́ ká rí bí àwọn akéde kan ṣe sọ ohun tí wọ́n máa bá onílé jíròrò nígbà tí wọ́n bá pa dà wá lẹ́yìn tí wọ́n ti fi Ilé Ìṣọ́ àti ìwé Ìròyìn Ayọ̀ sóde. Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ: (8 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 7 ìpínrọ̀ 15 sí 27, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 66 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 120 àti Àdúrà