Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍRÀ 6-10

Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́

Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́

Ẹ́sírà ṣètò láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù

7:6, 22; 8:26, 27

  • Ẹ́sírà gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ Atasásítà Ọba kó lè pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú

  • Ọba “yọ̀ǹda gbogbo” ohun tí Ẹ́sírà “béèrè” láti fi kọ́ ilé Jèhófà, àwọn nǹkan bíi wúrà, fàdákà, àlìkámà, wáìnì, òróró, àti iyọ̀, ìṣirò gbogbo wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] bílíọ̀nù náírà

Ẹ́sírà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀

7:13; 8:21-23

  • Ìrìn àjò wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù máa nira

  • Ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà, ojú ọ̀nà yẹn sì tún léwu

  • Ìrìn àjò náà gbà tó oṣù mẹ́rin

  • Ó gba pé kí àwọn tó pa dà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ìtara fún ìjọsìn tòótọ́ àti ìgboyà

ÀWỌN NǸKAN TÍ Ẹ́SÍRÀ KÓ DÁNÍ NI . . .

Wúrà àti fàdákà tó wúwo tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlá [513] àpò sìmẹ́ǹtì Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó akọ erin ńlá mẹ́ta!

ÌṢÒRO TÍ ÀWỌN TÓ PA DÀ KOJÚ . . .

Àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí, ojú ọjọ́ nínú aṣálẹ̀, àwọn ẹranko eléwu