Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Sọ Ohun Tó O Máa Bá Onílé Jíròrò Nígbà Tó O Bá Pa Dà Wá

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Sọ Ohun Tó O Máa Bá Onílé Jíròrò Nígbà Tó O Bá Pa Dà Wá

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:

A máa ń fẹ́ bomi rin irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn. (1Kọ 3:6) Tá a bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ó máa dáa ká bi ẹni náà ní ìbéèrè kan tá a máa dáhùn nígbà tá a bá pa dà wá. Èyí á jẹ́ kó máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí a máa pa dà wá, á sì tún jẹ́ kó rọrùn fún wa láti múra ìpadàbẹ̀wò náà sílẹ̀. Nígbà tá a bá pa dà lọ, a lè sọ fún un pé ìbéèrè tá a béèrè lọ́jọ́ tá a kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀ la pa dà wá dáhùn.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Tó o bá ń múra bó o ṣe máa wàásù láti ilé-dé-ilé sílẹ̀, tún múra ìbéèrè tí wàá dáhùn nígbà ìpadàbẹ̀wò sílẹ̀. Ó lè jẹ́ ìbéèrè tí ìdáhùn rẹ̀ wà nínú ìwé tó o fún onílé. Ó sì lè jẹ́ ìbéèrè tí ìdáhùn rẹ̀ wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí wàá fún onílé nígbà tó o bá pa dà lọ.

  • Kó o tó parí ìjíròrò rẹ nígbà àkọ́kọ́ tó o bá ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kó mọ̀ pé wàá tún fẹ́ pa dà wá nígbà míì, kó o sì sọ ìbéèrè kan tó o ti múra sílẹ̀ tí wàá pa dà wá dáhùn. Tó bá ṣeé ṣe, gba àdírẹ́sì rẹ̀.

  • Tó o bá bá ẹni náà ṣàdéhùn pé wàá pa dà wá, má ṣe yẹ àdéhùn rẹ.Mt 5:37.