January 4 SÍ 10
2 KÍRÓNÍKÀ 29-32
Orin 114 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìjọsìn Tòótọ́ Gba Ìsapá”: (10 min.)
2Kr 29:
10-17 —Hesekáyà fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe ìjọsìn tòótọ́, ó sì ṣàṣeyọrí 2Kr 30:
5, 6, 10-12 —Hesekáyà ní kí gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run 2Kr 32:
25, 26 —Hesekáyà tó jẹ́ agbéraga tẹ́lẹ̀ yí pa dà di onírẹ̀lẹ̀ (w05 10/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 20)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
2Kr 29:11
—Báwo ni Hesekáyà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́? (w13 11/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 6 àti 7) 2Kr 32:
7, 8 —Kí ni ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú? (w13 11/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 17) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: 2Kr 31:
1-10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò àkọ́kọ́ tá a pè ní Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò Láti fi Ilé Ìṣọ́ Lọni, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú fídíò náà. Pe àfíyèsí àwọn ará sí ọ̀nà tí akéde náà gbà sọ ohun tó máa bá onílé jíròrò nígbà tó bá pa dà wá. Ohun kan náà ni kó o ṣe pẹ̀lú fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kejì àti ti ìwé Ìròyìn Ayọ̀. Tọ́ka sí àkòrí náà, “Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 127
“Àǹfààní Tá A Ní Láti Kọ́ Àwọn Ibi Tí A Ti Ń Ṣe Ìjọsìn Tòótọ́ Ká sì Máa Bójú Tó Wọn”: (15 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn tó ti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sọ ayọ̀ tí wọ́n rí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Fi ọ̀rọ̀ wá arákùnrin tó ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́nu wò ní ṣókí, kó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ètò tí ìjọ yín ṣe.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 6 ìpínrọ̀ 1 sí 14 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 142 àti Àdúrà
Ìránnilétí: Jọ̀wọ́ jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.