Ọlọ́run San Hesekáyà Lẹ́san Torí Pé Ó Nígbàgbọ́
Senakéríbù Ọba Ásíríà rán Rábúṣákè sí Jerúsálẹ́mù, ó ní káwọn ará ìlú náà juwọ́ sílẹ̀ fún òun. Àwọn ará Ásíríà lo onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti kó àwọn Júù láyà jẹ, kí wọ́n báa lè juwọ́ sílẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n bá wọn jagun.
-
Íjíbítì pàápàá kò lè gbà yín sílẹ̀.—Ais 36:6
-
Jèhófà kò ní jà fún yín, torí pé inú rẹ̀ kò dùn sí yín.—Ais 36:7, 10
-
Àwọn ọmọ ogun Ásíríà lágbára gan-an, ọwọ́ kan ni wọ́n máa pa yín rẹ́.—Ais 36:8, 9
-
Ìgbésí ayé yín á dẹrùn tẹ́ ẹ bá juwọ́ sílẹ̀ fún Ásíríà.—Ais 36:16, 17