January 23-29
Aísáyà 38-42
Orin 78 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Ń Fi Agbára fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀”: (10 min.)
Ais 40:25, 26—Jèhófà ni Orísun gbogbo agbára (ip-1 409-410 ¶23-25)
Ais 40:27, 28—Jèhófà ń rí gbogbo ohun tí à ń fara dà àti ìyà tó ń jẹ wá (ip-1 413 ¶27)
Ais 40:29-31—Jèhófà máa ń fún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e lágbára (ip-1 413-415 ¶29-31)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ais 38:17—Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ju àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ẹ̀yìn rẹ̀? (w03 7/1 18 ¶17)
Ais 42:3—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jésù lára? (w15 2/15 8 ¶13)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 40:6-17
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 38-39 ¶6-7—Ṣe àṣefihàn béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 68
“Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Kristẹni Tí Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni Sí”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò náà Wọ́n Ní Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pa Dà Sílé Ẹjọ́ Nílùú Taganrog—Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Báyìí?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 7 ¶10-18, the box “Àwọn Ètò Orí Rédíò WBBR,” and the box “Àpéjọ Àgbègbè Mánigbàgbé”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 9 àti Àdúrà