MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Kristẹni Tí Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni Sí
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Sátánì máa ṣe inúnibíni sí wa, kó lè dá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dúró. (Jo 15:20; Iṣi 12:17) Báwo la ṣe lè ran àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí láwọn orílẹ̀-èdè míì lọ́wọ́? A lè máa gbàdúrà fún wọn. “Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.”—Jak 5:16.
Kí la lè sọ nínú àdúrà wa? A lè bẹ Jèhófà pé kó fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yìí ní ìgboyà, kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má ṣe fòyà. (Ais 41:10-13) A tún lè gbàdúrà pé kí àwọn aláṣẹ máa fi ojú tó tọ́ wo iṣẹ́ ìwàásù wa, “kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́.”—1Ti 2:1, 2.
Nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí Pọ́ọ̀lù àti Pétérù, àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dárúkọ wọn nínú àdúrà. (Iṣe 12:5; Ro 15:30, 31) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò mọ orúkọ àwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí lóde òní, ǹjẹ́ a lè dárúkọ ìjọ wọn, orílẹ̀-èdè tàbí àgbègbè tí wọ́n wà nínú àdúrà wa?