January 9-15
AÍSÁYÀ 29-33
Orin 123 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ọba Kan Yóò Jẹ fún Òdodo”: (10 min.)
Ais 32:1—Jésù Kristi ni Ọba tó máa jẹ fún òdodo (w14 2/15 6 ¶13)
Ais 32:2—Jésù tó ti di ọba pèsè àwọn ọmọ aládé tó máa bójú tó agbo rẹ̀ (ip-1 332-334 ¶7-8)
Ais 32:3, 4—Àwọn èèyàn Jèhófà ń rí ìtọ́ni àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbà tó jẹ́ kí wọ́n lè jẹ́ olódodo (ip-1 334-335 ¶10-11)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ais 30:21—Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀? (w14 8/15 21 ¶2)
Ais 33:22—Ìgbà wo ni Jèhófà di Onídàájọ́, Ẹni tí ń fúnni ní ìlànà àgbékalẹ̀, àti Ọba fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, báwo ló sì ṣe dì í? (w14 10/15 14 ¶4)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 30:22-33
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp17.1—Fún onílé tínú ń bí lésì.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp17.1—Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ látorí fóònù tàbí tablet.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 31-32 ¶12-13—Ṣe àṣefihàn béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 119
“Ibi Ìfarapamọ́sí Kúrò Lọ́wọ́ Ẹ̀fúùfù” (Ais 32:2): (9 min.) Jẹ́ káwọn ará wo fídíò yìí.
Máa Fetí Sílẹ̀ Nípàdé: (6 min.) Jẹ́ káwọn ará wo fídíò Máa Fetí Sílẹ̀ Nípàdé. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé tó o ti yàn tẹ́lẹ̀ wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n láwọn ìbéèrè yìí: Kí ló lè mú kẹ́ ẹ má fetí sílẹ̀ nípàdé? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ ká ní Nóà kò fetí sílẹ̀ nígbà tí Jèhófà ń ṣàlàyé bó ṣe máa kan ọkọ̀ áàkì fún un? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọdé máa fetí sílẹ̀ nípàdé?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 6 ¶16-24 àti àpótí “Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 40 àti Àdúrà