ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI January 2018
Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ
Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ nípa bí Bíbélì ṣe wúlò tó lóde òní.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”
Jòhánù jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ìfẹ́ Ọlọ́run ló sì fi ayé rẹ̀ ṣe. Lónìí, tá a bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a máa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè
Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé àìní tẹ̀mí ń jẹ wá lọ́kàn? Báwo la ṣe lè sunwọ̀n sí i nínu bá a ṣe ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Báwo Lo Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àlàáfíà Pẹ̀lú Arákùnrin Rẹ?
Kí ni Jésù ń kọ́ wa nípa wíwá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa àti irú ìjọsìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Máa Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́
Nínú gbogbo ohun tá a lè gbàdúrà fún, èwo ló ṣe pàtàkì jù?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn
Nínú ìwàásù Orí Òkè, kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n dẹ́kun ṣíṣàníyàn?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jésù Fẹ́ràn Àwọn Èèyàn
Bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn fi hàn pé alágbára ni, àmọ́ ní pàtàkì, ó fi hàn pé ó láàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gidigidi.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jésù Mú Kí Ara Tù Wá
Nígbà tá a ṣe ìrìbọmi, a di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, a sì ti gba àjàgà rẹ̀, àtìgbà náà la ti ń ṣe iṣẹ́ ńlá tó gbé fún wa, iṣẹ́ náà ń mára tuni, ó sì máa ń yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún.