January 1-7
MÁTÍÙ 1-3
Orin 14 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Mátíù.]
Mt 3:1, 2—Jòhánù arinibọmi kéde pé ẹni tó máa jẹ́ Alákòóso Ìjọba ọ̀run lọ́jọ́ iwájú kò ní pẹ́ dé (“ìwàásù,” “Ìjọba,” “Ìjọba ọ̀run,” “ti sún mọ́lé” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:1, 2, nwtsty)
Mt 3:4—Jòhánù jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ìfẹ́ Ọlọ́run ló sì fi ayé rẹ̀ ṣe (“Aṣọ àti Ìrísí Jòhánù Arinibọmi,” “Eéṣú,” “Oyin Ìgàn” àwòrán àti fídíò lórí Mt 3:4, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 1:3—Kí nìdí tí orúkọ àwọn obìnrin márùn-ún fi wà láàárín àwọn ọkùnrin tó wà ní ìlà ìdílé Jésù? (“Támárì” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 1:3, nwtsty)
Mt 3:11—Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n ri ẹnì kan bọ omi pátápátá? (“batisí yín” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:11, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 1:1-17
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 39-40 ¶6-7
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún: (15 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún, lẹ́yìn náà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn kí wọ́n sì sọ àwọn ìrírí tó ta yọ tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 2, ¶1-11
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 137 àti Àdúrà