Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 1-3

“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”

“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”

3:4

  • Bí Jòhánù ṣe máa ń múra àti bó ṣe rí fi hàn pé ó jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ìfẹ́ Ọlọ́run ló sì fi ayé rẹ̀ ṣe

  • Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni Jòhánù ní bó ṣe palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù, èyí sì ju ohun yòówù tó yááfì lọ

Tá a bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a máa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn sì máa fún wa láyọ̀. A lè jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn láwọn ọ̀nà yìí . . .

  • mọ àwọn ohun tó o nílò gangan

  • má ṣe ra àwọn ohun tí kò pọn dandan

  • gbé ìṣirò lé bó o ṣe máa ná owó rẹ

  • fún àwọn míì ní àwọn nǹkan tí o kò nílò mọ́ tàbí kó o tà wọ́n

  • san gbogbo gbèsè tó o jẹ

  • dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ò ń ṣe kù àti àkókò tó ò ń lò

Eéṣú àti oyin ìgàn ni Jòhánù máa ń jẹ

Tí mo bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ mi lọ́rùn, àfojúsùn wo ni ọwọ́ mi lè tẹ̀?