January 15-21
MÁTÍÙ 6-7
Orin 21 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́”: (10 min.)
Mt 6:10—Ìjọba náà wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ nínú àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ, ìyẹn fi hàn pé ó ṣe pàtàkì (bh 169 ¶12)
Mt 6:24—A ò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún “Ọrọ̀” (“sìnrú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 6:24, nwtsty)
Mt 6:33—Jèhófà máa bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn (“Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá,” “ìjọba náà,” “rẹ̀” “òdodo” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 6:33, nwtsty; w16.07 12 ¶18)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 7:12—Báwo la ṣe lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí tá a bá ń múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fẹ́ lò lóde ẹ̀rí sílẹ̀? (w14 5/15 14 ¶14-16)
Mt 7:28, 29—Báwo ni ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jésù ṣe rí lára àwọn ogunlọ́gọ̀, kí sì nìdí? (“háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀,” “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,” “kì í sì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin wọn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 7:28, 29, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 6:1-18
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni tó o kọ́kọ́ wàásù fún kò sí nílé, àmọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan lo bá.
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò náà Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Àwọn Àfiwé Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Lò—Ẹ Kíyè Sí Àwọn Ẹyẹ àti Òdòdó Lílì.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 3 ¶1-7 àti àpótí ojú ìwé 29 [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ jíròrò àpótí tàbí àfikún àlàyé]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 132 àti Àdúrà