MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn
Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín.” (Mt 6:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò sí bí àwa èèyàn aláìpé tí à ń gbé nínú ayé Sátánì yìí ò ṣe ní máa ṣàníyàn, síbẹ̀ ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n yẹra fún àníyàn àṣejù. (Sm 13:2) Kí nìdí? Ìdí ni pé tí èèyàn bá ń ṣe àníyàn nípa àwọn nǹkan tó nílò, onítọ̀hún ò ní lè pọkàn pọ̀, á sì nira fún un láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. (Mt 6:33) Àwọn ohun tí Jésù tún sọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti dẹ́kun ṣíṣe àníyàn tí kò pọn dandan.
-
Mt 6:26—Kí la lè rí kọ́ tá a bá ń kíyè sí àwọn ẹyẹ? (w16.07 9-10 ¶11-13)
-
Mt 6:27—Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àníyàn àṣejù máa ń fi àkókò àti okun ẹni ṣòfò? (w05 11/1 22 ¶5)
-
Mt 6:28-30—Kí la lè rí kọ́ lára àwọn òdòdó lílì pápá? (w16.07 10-11 ¶15-16)
-
Mt 6:31, 32—Àwọn ọ̀nà wo ni àwa Kristẹni fi yàtọ̀ sí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò nígbàgbọ́? (w16.07 11 ¶17)
Àwọn nǹkan wo ni mi ò fẹ́ máa ṣàníyàn nípa rẹ̀?