January 22-28
MÁTÍÙ 8-9
Orin 17 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jésù Fẹ́ràn Àwọn Èèyàn”: (10 min.)
Mt 8:1-3—Jésù ṣàánú adẹ́tẹ̀ kan lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (“ó fọwọ́ kàn án,” “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 8:3, nwtsty)
Mt 9:9-13—Jésù fẹ́ràn àwọn èèyàn táwọn kan kà sí gbáàtúù (“rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì,” “àwọn agbowó orí” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 9:10, nwtsty)
Mt 9:35-38—Ìfẹ́ ló mú kí Jésù wàásù ìhìn rere kódà nígbà tó ti rẹ̀ ẹ́, ìfẹ́ ló tún mú kó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ jáde (“àánú wọn ṣe é” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 9:36, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 8:8-10—Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù bá ọ̀gágun náà sọ? (w02 8/15 13 ¶16)
Mt 9:16, 17—Kí ni Jésù fẹ́ ká fi sọ́kàn nígbà tó sọ àkàwé méjì yìí? (jy 70 ¶6)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 8:1-17
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Pe ẹni náà wá sí ìpàdé.
Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa lò, fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 44 ¶18-19
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
‘Dájúdájú Ọlọ́run Fi Í Ṣe Olúwa àti Kristi’—Látinú Apá 1: (15 min.) Ìjíròrò. Lẹ́yìn tí ẹ bá ka Mátíù 9:18-25 tí ẹ sì ti wo fídíò náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun bìkítà fún obìnrin tó ń ṣàìsàn àti fún Jáírù?
Ipa wo ni ohun tí o kà yìí ní lórí ojú tí o fi ń wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ọjọ́ iwájú lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bíi ti Jésù?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 3 ¶8-15 àti àpótí ojú ìwé 30 [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ jíròrò àpótí tàbí àfikún àlàyé]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 95 àti Àdúrà