Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 8-9

Jésù Fẹ́ràn Àwọn Èèyàn

Jésù Fẹ́ràn Àwọn Èèyàn

Mátíù orí 8 àti 9 sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ní àgbègbè Gálílì. Bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn fi hàn pé alágbára ni, àmọ́ ní pàtàkì, ó fi hàn pé ó láàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gidigidi.

  1. Jésù wo adẹ́tẹ̀ kan sàn.​—Mt 8:1-3.

  2. Jésù wo ìránṣẹ́ ọ̀gá ológun kan sàn.​—Mt 8:5-13

    Ó wo ìyá ìyàwó Pétérù sàn.​—Mt 8:​14, 15

    Ó lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ó sì mú àwọn aláìsàn lára dá. ​—Mt 8:​16, 17

  3. Jésù lé àwọn ẹ̀mí burúkú jáde sáàárín àwọn ẹlẹ́dẹ̀.​—Mt 8:​28-32

  4. Jésù mú arọ lára dá.​—Mt 9:1-8.

    Ó mú obìnrin kan tó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀ lára dá, ó tún jí ọmọbìnrin Jáírù dìde.​—Mt 9:18-26

    Ó la ojú afọ́jú, ó mú kí odi sọ̀rọ̀.​—Mt 9:27-34

  5. Jésù rìnrìn-àjò kárí àwọn ìlú àti abúlé, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti òkùnrùn sàn.​—Mt 9:35, 36

Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa ṣàánú àwọn èèyàn, kí n sì nífẹ̀ẹ́ wọn?