January 29–February 4
MÁTÍÙ 10-11
Orin 4 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jésù Mú Kí Ara Tù Wá”: (10 min.)
Mt 10:29, 30—Jésù fi dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an, èyí sì ń mú kí ara tù wá (“ológoṣẹ́,” “ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré,” “gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà” àlàyé ọ̀rọ̀ àti “Ológoṣẹ́” àwòrán àti fídíò lórí Mt 10:29, 30, nwtsty)
Mt 11:28—Bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà ń tù wá lára (“di ẹrù wọ̀ lọ́rùn,” “èmi yóò sì tù yín lára” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 11:28, nwtsty)
Mt 11:29, 30—Bá a ṣe ń fi ara wa sábẹ́ àṣẹ àti ìtọ́sọ́nà Kristi ń tù wá lára (“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 11:29, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 11:2, 3—Kí nìdí tí Jòhánù Arinibọmi fi béèrè ìbéèrè yìí? (jy 96 ¶2-3)
Mt 11:16-19—Kí ni àwọn ẹsẹ yìí túmọ̀ sí? (jy 98 ¶1-2)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 11:1-19
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Kẹta: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ìwọ ni kó o yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa lò àti ìbéèrè fún ìgbà míì.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 42-43 ¶15-16—Pe ẹni náà wá sí ìpàdé.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Ń Tu “Àwọn Tí Ń Ṣe Làálàá, Tí A Sì Di Ẹrù Wọ̀ Lọ́rùn” Nínú: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará pé:
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó jẹ́ kí àwọn èèyàn nílò ìtura?
Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ń lo ètò rẹ̀ láti tù wá lára?
Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe máa ń tù wá lára?
Báwo la ṣe lè mú kí ara tu àwọn ẹlòmíì?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 3, ¶16-21
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 138 àti Àdúrà