Jésù Mú Kí Ara Tù Wá
“Àjàgà mi jẹ́ ti inú rere”
Torí pé Jésù jẹ́ káfíńtà, ó mọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àjàgà, tí wọ́n á fi aṣọ tàbí awọ wé e kí ó lè tura fún ẹni tó bá gbé e. Nígbà tá a ṣe ìrìbọmi, a di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, a sì ti gba àjàgà rẹ̀, àtìgbà náà la ti ń ṣe iṣẹ́ ńlá tó gbé fún wa, iṣẹ́ náà ń mára tuni, ó sì máa ń yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún.
Àwọn ìbùkún wo lo ti rí látìgbà tó o ti gba àjàgà Jésù?