January 8-14
MÁTÍÙ 4-5
Orin 82 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè”: (10 min.)
Mt 5:3—A máa láyọ̀ tá a bá ń jẹ́ kí nǹkan tẹ̀mí jẹ wá lọ́kàn (“Aláyọ̀,” “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:3, nwtsty)
Mt 5:7—A máa láyọ̀ tá a bá jẹ́ aláàánú tá a sì ń ṣoore fáwọn èèyàn (“aláàánú” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:7, nwtsty)
Mt 5:9—A máa láyọ̀ tá a bá jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà (“ẹlẹ́mìí àlàáfíà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:9, nwtsty; w07 12/1 17)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Mt 4:9—Kí ni Sátánì fẹ́ kí Jésù ṣe nígbà tó dẹ ẹ́ wò? (“jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 4:9, nwtsty)
Mt 4:23—Iṣẹ́ pàtàkì méjì wo ni Jésù ṣe? (“ó ń kọ́ni . . . ó sì ń wàásù” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 4:23, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 5:31-48
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Wo Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w16.03 31-32—Àkòrí: Nígbà Tí Sátánì Dán Jésù Wò, Ṣé Tẹ́ńpìlì Gangan Ló Mú Jésù Lọ?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Wọ́n Ti Ṣe Inúnibíni sí Nítorí Òdodo: (9 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ìdílé Namgung: Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀.
“Báwo Lo Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àlàáfíà Pẹ̀lú Arákùnrin Rẹ?” (6 min.) Ìjíròrò. Ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé ìdáhùn tó gbẹ̀yìn ní apá méjèèjì ni ohun tó yẹ kí èèyàn ṣe.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 2 ¶12-21 àti àpótí ojú ìwé 24 [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ jíròrò àpótí tàbí àfikún àlàyé]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 141 àti Àdúrà